EWÌ SỌ̀RỌ̀ SÓKÈ

EWÌ SỌ̀RỌ̀ SÓKÈ

ÀṢÀYÀN EWÌ FÚN ÌGBÌYÀNJÚ ÀWỌN Ọ̀DỌ̀ NÍ ORÍLÈ-ÈDÈ NÀÍJÍRÍÀ

GlobeEdit ( 2021-04-13 )

€ 35,90

Buy at the MoreBooks! Shop

EWÌ SỌ̀RỌ̀ SÓKÈ: Ó jẹ́ ohùn ìdùnnú fún mí púpọ̀ láti kọ ìwé àkójọpọ̀ ewì yìí. Àwọn ewì jẹ ohun àbálàye tí ó jẹ ọmọ Yorùbá lógún. Ní ayé àtijọ́ ní ilè Yorùbá, ò un ni àwọn bàbá-ńlá wa máa ń lò fún ìmọ̀, ìmọ̀ràn àti ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n won kìí kọọ́ sílẹ̀ nítorí pé, wọn kò ní ìmọ̀ mọ̀ọ́kọ–mọ̀ọ́kà rárá. Orísírísí àwọn ewì ni ó wa, Èrò ọkàn mí ní pé a ó gbàdùn ìwé àkójọpọ̀ ewì yìí. "Ewì Sọ̀rọ̀ Sókè!" ni àkọlé Ìwé Ìṣípayá Ewi Yorùbá yìí (Poetry On Speak Up!). Àkọlé ìwé yìí jẹ jáde nínú ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Nàíjíríà (A popular phrase that has informally become the name of the millennial slang of generations in Nigeria). Àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwọde #EndSARS ní Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà: ní ìpínlè Èkó, Ekiti, Ọ̀yọ́, Ondo, Osun, Kwara ati Abuja lati bá àwọn olórí àti àwọn ọmọ ilu sọ̀rọ̀ ní ọdún 2020. Kí ni ìtumọ̀ "Sọ̀rọ̀ Sókè" àti Ìwọ́de tí àwọn ọ̀dọ́ n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ yìí? Wọ́n fi Ìwọ́de #EndSARS yìí sọ pé kí àwọn Ọlọpa má ṣe pa àwọn ará ìlú mọ́, pàtàkì jù lọ àwọn ọ̀dọ́ àti pé kí olúkúlùkù sọ àwọn ẹ̀dùn ọkàn wọn gbogbo jáde ni orílẹ̀-èdè NÀÍJÍRÍÀ. Naijiria ni orílè-èdè tí ó ní ibùgbé púpò jùlọ ní Afrika, ó tún jẹ́ ìkẹjọ ní àgbáyé, bẹ si ní ó jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ní àwọn ènìyàn dúdú jùlọ pẹ̀lú.

Book Details:

ISBN-13:

978-620-0-62213-6

ISBN-10:

6200622132

EAN:

9786200622136

Book language:

Afrikaans

By (author) :

Funmilayo Adesanya-Davies

Number of pages:

76

Published on:

2021-04-13

Category:

Sociology